O. Daf 62 - Yoruba BibleỌlọrun ni Ààbò Wa 1 Ọlọrun nìkan ni mo fi sùúrù gbẹ́kẹ̀lé; ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìgbàlà mi ti wá. 2 Òun nìkan ni àpáta ati olùgbàlà mi, òun ni odi mi, a kì yóo tì mí kúrò. 3 Yóo ti pẹ́ tó, tí gbogbo yín yóo dojú kọ ẹnìkan ṣoṣo, láti pa, ẹni tí kò lágbára ju ògiri tí ó ti fẹ́ wó lọ, tabi ọgbà tí ó fẹ́ ya? 4 Wọ́n fẹ́ ré e bọ́ láti ipò ọlá rẹ̀. Inú wọn a máa dùn sí irọ́. Wọ́n ń fi ẹnu wọn súre, ṣugbọn ní ọkàn wọn, èpè ni wọ́n ń ṣẹ́. 5 Ọlọrun nìkan ni mo fi sùúrù gbẹ́kẹ̀lé, nítorí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìrètí mi ti wá. 6 Òun nìkan ni àpáta ati olùgbàlà mi, òun ni odi mi, a kì yóo tì mí kúrò. 7 Ọwọ́ Ọlọrun ni ìgbàlà ati ògo mi wà; òun ni àpáta agbára mi ati ààbò mi. 8 Ẹ gbẹ́kẹ̀lé e nígbà gbogbo, ẹ̀yin eniyan; ẹ tú ẹ̀dùn ọkàn yín palẹ̀ níwájú rẹ̀; OLUWA ni ààbò wa. 9 Afẹ́fẹ́ lásán ni àwọn mẹ̀kúnnù; ìtànjẹ patapata sì ni àwọn ọlọ́lá; bí a bá gbé wọn lé ìwọ̀n, wọn kò lè tẹ̀wọ̀n; àpapọ̀ wọn fúyẹ́ ju afẹ́fẹ́ lọ. 10 Má gbẹ́kẹ̀lé ìlọ́ni-lọ́wọ́-gbà, má sì fi olè jíjà yangàn; bí ọrọ̀ bá ń pọ̀ sí i, má gbé ọkàn rẹ lé e. 11 Ọlọrun ti sọ̀rọ̀ níbìkan, mo sì ti gbọ́ ọ bí ìgbà mélòó kan pé, Ọlọrun ló ni agbára; 12 ati pé, tìrẹ, OLUWA ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀. Ò máa san ẹ̀san fún eniyan gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ bá ti rí. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria