O. Daf 61 - Yoruba BibleAdura Ààbò 1 Gbọ́ igbe mi, Ọlọrun, fetí sí adura mi. 2 Láti ọ̀nà jíjìn réré ni mo ti ké pè ọ́, nígbà tí àárẹ̀ mú mi. Tọ́ mi lọ sí ibi àpáta tí ó ga jù mí lọ, 3 nítorí ìwọ ni ààbò mi, ìwọ ni ilé ìṣọ́ tí ó lágbára láti dáàbò bò mí lọ́wọ́ ọ̀tá. 4 Jẹ́ kí n máa gbé inú àgọ́ rẹ títí lae, kí n lè máa wà láìléwu lábẹ́ ààbò ìyẹ́ rẹ. 5 Nítorí ìwọ, Ọlọrun, ti gbọ́ ẹ̀jẹ́ tí mo jẹ́; o ti fún mi ní ogún tí o pèsè fún àwọn tí ó bẹ̀rù orúkọ rẹ. 6 Jẹ́ kí ẹ̀mí ọba ó gùn; kí ó pẹ́ láyé kánrinkése. 7 Kí ó máa gúnwà níwájú Ọlọrun títí lae; máa fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, ati òtítọ́ rẹ ṣọ́ ọ. 8 Bẹ́ẹ̀ ni n óo máa kọ orin ìyìn orúkọ rẹ títí lae, nígbà tí mo bá ń san ẹ̀jẹ́ mi lojoojumọ. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria