O. Daf 60 - Yoruba BibleAdura fún Ìgbàlà 1 Ọlọrun, o ti kọ̀ wá sílẹ̀, o ti wó odi wa; o ti bínú, dákun, mú wa bọ̀ sípò. 2 O ti mú kí ilẹ̀ mì tìtì; o ti mú kí ó yanu; dí gbogbo ibi tí ilẹ̀ ti ya, nítorí pé ó ń mì. 3 O ti jẹ́ kí àwọn eniyan rẹ ní ọpọlọpọ ìnira, o ti fún wa ní ọtí mu tóbẹ́ẹ̀ tí à ń ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n. 4 O ti ta àsíá ogun fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ, kí wọ́n baà lè rí ààbò lọ́wọ́ ọfà ọ̀tá. 5 Kí á lè gba àyànfẹ́ rẹ là, fi ọwọ́ agbára rẹ ṣẹgun fún wa, kí o sì dá wa lóhùn. 6 Ọlọrun ti sọ̀rọ̀ ninu ilé mímọ́ rẹ̀, ó ní, “Tayọ̀tayọ̀ ni n óo fi pín Ṣekemu, n óo sì pín àfonífojì Sukotu. 7 Tèmi ni Gileadi, tèmi sì ni Manase; Efuraimu ni àkẹtẹ̀ àṣíborí mi, Juda sì ni ọ̀pá àṣẹ mi. 8 Moabu ni ìkòkò ìwẹsẹ̀ mi; lórí Edomu ni n óo bọ́ bàtà mi lé; n óo sì hó ìhó ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí Filistia.” 9 Ta ni yóo mú mi wọ inú ìlú olódi náà? Ta ni yóo mú mi lọ sí Edomu? 10 Ọlọrun, o kò ha ti kọ̀ wá sílẹ̀? Ọlọrun, o ò bá àwọn ọmọ ogun wa jáde lọ sójú ogun mọ́. 11 Ràn wá lọ́wọ́, bá wa gbógun ti àwọn ọ̀tá wa, nítorí pé asán ni ìrànlọ́wọ́ eniyan. 12 Pẹlu àtìlẹ́yìn Ọlọrun a óo ṣe akin, nítorí òun ni yóo tẹ àwọn ọ̀tá wa mọ́lẹ̀. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria