O. Daf 57 - Yoruba BibleAdura Ìrànlọ́wọ́ 1 Ṣàánú mi, Ọlọrun, ṣàánú mi, nítorí ìwọ ni ààbò mi; abẹ́ òjìji apá rẹ ni n óo fi ṣe ààbò mi, títí gbogbo àjálù wọnyi yóo fi kọjá. 2 Mo ké pe Ọlọrun Ọ̀gá Ògo, Ọlọrun tí ó mú èrò rẹ̀ ṣẹ fún mi. 3 Yóo ranṣẹ láti ọ̀run wá, yóo gbà mí là, yóo dójú ti àwọn tí ń lépa ẹ̀mí mi. Ọlọrun yóo fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́ rẹ̀ hàn! 4 Ààrin àwọn kinniun ni mo dùbúlẹ̀ sí, àwọn tí ń jẹ eniyan ní ìjẹ ìwọ̀ra; eyín wọn dàbí ọ̀kọ̀ ati ọfà, ahọ́n wọn sì dàbí idà. 5 Gbé ara rẹ ga, Ọlọrun, gbé ara rẹ ga ju ọ̀run lọ, kí ògo rẹ sì tàn ká gbogbo ayé. 6 Wọ́n dẹ àwọ̀n sí ojú ọ̀nà mi; ìpọ́njú dorí mi kodò. Wọ́n gbẹ́ kòtò sílẹ̀ dè mí, ṣugbọn àwọn fúnra wọn ni wọ́n jìn sí i. 7 Ọkàn mi dúró ṣinṣin, Ọlọrun, ọkàn mi dúró ṣinṣin! N óo kọrin, n óo sì máa yìn ọ́. 8 Jí, ìwọ ọkàn mi! Ẹ jí, ẹ̀yin ohun èlò orin, ati hapu, èmi alára náà yóo jí ní òwúrọ̀ kutukutu. 9 OLUWA, n óo máa fi ọpẹ́ fún ọ láàrin àwọn eniyan; n óo sì máa kọrin ìyìn sí ọ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè. 10 Nítorí pé ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tóbi, ó ga ju ọ̀run lọ, òtítọ́ rẹ sì kan ojú ọ̀run. 11 Gbé ara rẹ ga, Ọlọrun, gbé ara rẹ ga ju ọ̀run lọ, kí ògo rẹ sì tàn ká gbogbo ayé. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria