Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

O. Daf 54 - Yoruba Bible


Adura Ààbò

1 Fi agbára orúkọ rẹ gbà mí, Ọlọrun, fi ipá rẹ dá mi láre.

2 Gbọ́ adura mi, Ọlọrun; tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ ẹnu mi.

3 Nítorí pé àwọn agbéraga dìde sí mi, àwọn ìkà, aláìláàánú sì ń lépa ẹ̀mí mi; wọn kò bìkítà fún Ọlọrun.

4 Ṣugbọn Ọlọrun ni olùrànlọ́wọ́ mi, OLUWA ni ó gbé ẹ̀mí mi ró.

5 Yóo san ẹ̀san ibi fún àwọn ọ̀tá mi; OLUWA, nítorí òtítọ́ rẹ, pa wọ́n run.

6 N óo rú ẹbọ ọrẹ àtinúwá sí ọ, n óo máa yin orúkọ rẹ, OLUWA, nítorí pé ó dára bẹ́ẹ̀.

7 O ti yọ mí ninu gbogbo ìṣòro mi, mo sì ti fi ojú mi rí ìṣubú àwọn ọ̀tá mi.

Bible Society of Nigeria © 1900/2010

Bible Society of Nigeria
Lean sinn:



Sanasan