O. Daf 53 - Yoruba BibleÈrè Òmùgọ̀ (Orin 14) 1 Òmùgọ̀ sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé, “Kò sí Ọlọrun.” Wọ́n bàjẹ́, ohun ìríra ni wọ́n ń ṣe, kò sì sí ẹnìkan ninu wọn tí ń ṣe rere. 2 Ọlọrun bojú wo àwọn ọmọ eniyan láti ọ̀run wá, ó ń wò ó bí àwọn kan bá wà tí òye yé, àní, bí àwọn kan bá wà tí ń wá Ọlọrun. 3 Gbogbo wọn ni ó ti yapa; tí wọn sì ti bàjẹ́, kò sí ẹnìkan tí ń ṣe rere, kò sí, bó tilẹ̀ jẹ́ ẹnìkan ṣoṣo. 4 Ṣé gbogbo àwọn aṣebi kò gbọ́n ni? Àwọn tí ń jẹ eniyan mi bí ẹni jẹun, àní àwọn tí kì í ké pe Ọlọrun. 5 Ẹ wò wọ́n, bí wọ́n ṣe wà ninu ẹ̀rù ńlá, ẹ̀rù tí kò tíì sí irú rẹ̀ rí! Nítorí Ọlọrun yóo fọ́n egungun àwọn ọ̀tá rẹ̀ ká; ojú óo tì wọ́n, nítorí Ọlọrun ti kọ̀ wọ́n. 6 Ìbá ti dára tó, kí ìgbàlà Israẹli ti Sioni wá! Nígbà tí Ọlọrun bá dá ire àwọn eniyan rẹ̀ pada, Jakọbu yóo yọ̀, inú Israẹli yóo sì dùn. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria