O. Daf 52 - Yoruba BibleÌdájọ́ ati Oore Ọ̀fẹ́ Ọlọrun 1 Ìwọ alágbára, kí ló dé tí o fi ń fọ́nnu, kí ló dé tí ò ń fọ́nnu tọ̀sán-tòru? Ẹni ìtìjú ni ọ́ lójú Ọlọrun. 2 Ò ń pète ìparun; ẹnu rẹ dàbí abẹ tí ó mú, ìwọ alárèékérekè. 3 O fẹ́ràn ibi ju ire lọ, o sì fẹ́ràn irọ́ ju òtítọ́ lọ. 4 O fẹ́ràn gbogbo ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́, Ìwọ ẹlẹ́tàn! 5 Nítòótọ́ Ọlọrun óo bá ọ kanlẹ̀, yóo gbá ọ mú, yóo sì fà ọ́ já kúrò ninu ilé rẹ; yóo fà ọ́ tu kúrò lórí ilẹ̀ alààyè. 6 Nígbà tí àwọn olódodo bá rí i, ẹ̀rù óo bà wọ́n, wọn óo fi rẹ́rìn-ín, wọn óo sì wí pé, 7 “Wo ẹni tí ó kọ̀, tí kò fi Ọlọrun ṣe ààbò rẹ̀, ṣugbọn ó gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ rẹ̀ tí ó pọ̀, ati jamba tí ó ń ta fún ẹlòmíràn.” 8 Ṣugbọn èmi dàbí igi olifi tútù tí ń dàgbà ninu ilé OLUWA, mo gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ Ọlọrun tí kì í yẹ̀, lae ati laelae. 9 N óo máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ títí lae, nítorí ohun tí o ṣe, n óo máa kéde orúkọ rẹ níwájú àwọn olùfọkànsìn rẹ, nítorí pé ó dára bẹ́ẹ̀. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria