O. Daf 5 - Yoruba BibleAdura Ààbò 1 Fetí sí ọ̀rọ̀ mi, OLUWA; kíyèsí ìmí ẹ̀dùn mi. 2 Fetí sí igbe mi, Ọba mi ati Ọlọrun mi, nítorí ìwọ ni mò ń gbadura sí. 3 OLUWA, o óo gbọ́ ohùn mi ní òwúrọ̀, ní òwúrọ̀ ni n óo máa sọ ẹ̀dùn ọkàn mi fún ọ; èmi óo sì máa ṣọ́nà. 4 Nítorí ìwọ kì í ṣe Ọlọrun tí inú rẹ̀ dùn sí ìwà burúkú; àwọn ẹni ibi kò sì lè bá ọ gbé. 5 Àwọn tí ń fọ́nnu kò lè dúró níwájú rẹ; o kórìíra gbogbo àwọn aṣebi. 6 O máa ń pa àwọn òpùrọ́ run; OLUWA, o kórìíra àwọn apani ati ẹlẹ́tàn. 7 Ṣugbọn nípa ọ̀pọ̀ ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, èmi óo wọ inú ilé rẹ; n óo fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ wólẹ̀, n óo sì kọjúsí tẹmpili mímọ́ rẹ. 8 OLUWA, tọ́ mi sọ́nà òdodo rẹ, nítorí àwọn ọ̀tá mi; jẹ́ kí ọ̀nà rẹ hàn kedere níwájú mi. 9 Nítorí kò sí òtítọ́ kan lẹ́nu wọn; ìparun ni ó wà ninu ọkàn wọn. Isà òkú tí ó yanu sílẹ̀ ni ọ̀fun wọn; ẹnu wọn kún fún ìpọ́nni ẹ̀tàn. 10 Dá wọn lẹ́bi, Ọlọrun, kí o sì fìyà jẹ wọ́n; jẹ́ kí ìgbìmọ̀pọ̀ wọn ó gbé wọn ṣubú. Ta wọ́n nù nítorí ọ̀pọ̀ ìrékọjá wọn, nítorí pé wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí ọ. 11 Ṣugbọn jẹ́ kí inú gbogbo àwọn tí ó sá di ọ́ ó dùn, kí wọn ó máa kọrin ayọ̀ títí lae. Dáàbò bò wọ́n, kí àwọn tí ó fẹ́ràn orúkọ rẹ sì máa yọ̀ ninu rẹ. 12 Nítorí ìwọ OLUWA a máa bukun àwọn olódodo; ò sì máa fi ojurere rẹ tí ó dàbí apata dáàbò bò wọ́n. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria