O. Daf 48 - Yoruba BibleOLUWA Tóbi 1 OLUWA tóbi, ó sì yẹ kí á máa yìn ín lọpọlọpọ ní ìlú Ọlọrun wa. 2 Òkè mímọ́ rẹ̀, tí ó ga, tí ó sì lẹ́wà, ni ayọ̀ gbogbo ayé. Òkè Sioni, ní àríwá, lọ́nà jíjìn réré, ìlú ọba ńlá. 3 Ninu ilé ìṣọ́ ìlú náà, Ọlọrun ti fi ara rẹ̀ hàn bí ibi ìsádi. 4 Wò ó! Àwọn ọba kó ara wọn jọ; wọ́n jùmọ̀ gbógun tì í. 5 Nígbà tí wọ́n fojú kàn án, ẹnu yà wọ́n, ìpayà mú wọn, wọ́n sì sá; 6 ìwárìrì mú wọn níbẹ̀; ìrora sì bá wọn bí obinrin tí ń rọbí. 7 Ó fọ́ wọn bí afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn tií fọ́ ọkọ̀ Taṣiṣi. 8 Bí a ti gbọ́, bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó rí, ní ìlú OLUWA àwọn ọmọ ogun, ní ìlú Ọlọrun wa: Ọlọrun fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ títí lae. 9 Ninu tẹmpili rẹ, Ọlọrun, à ń ṣe àṣàrò lórí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀. 10 Ọlọrun, ìyìn rẹ tàn ká, bí orúkọ rẹ ṣe tàn dé òpin ayé, iṣẹ́ rere kún ọwọ́ rẹ. 11 Jẹ́ kí inú òkè Sioni kí ó dùn, kí gbogbo Juda sì máa yọ̀ nítorí ìdájọ́ rẹ. 12 Ẹ rìn yí Sioni po; ẹ yí i ká; ẹ ka àwọn ilé ìṣọ́ rẹ̀; 13 ẹ ṣàkíyèsí odi rẹ̀; ẹ wọ inú gbogbo ilé ìṣọ́ rẹ̀ lọ, kí ẹ lè ròyìn fún ìran tí ń bọ̀ 14 pe: “Ọlọrun yìí ni Ọlọrun wa, lae ati laelae. Òun ni yóo máa ṣe amọ̀nà wa títí lae.” |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria