O. Daf 47 - Yoruba BibleỌba Àwọn Ọba 1 Ẹ pàtẹ́wọ́, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè; ẹ kọ orin ayọ̀, ẹ hó sí Ọlọrun. 2 Nítorí pé ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ni OLUWA, Ọ̀gá Ògo, Ọba ńlá lórí gbogbo ayé. 3 Ó tẹ àwọn orílẹ̀-èdè lórí ba fún wa, ó sì sọ àwọn orílẹ̀-èdè di àtẹ̀mọ́lẹ̀ fún wa. 4 Òun ni ó yan ilẹ̀ ìní wa fún wa, èyí tí àwọn ọmọ Jakọbu, àyànfẹ́ rẹ̀, fi ń yangàn. 5 A ti gbé Ọlọrun ga pẹlu ìhó ayọ̀, a ti gbé OLUWA ga pẹlu ìró fèrè. 6 Ẹ kọ orin ìyìn sí Ọlọrun, ẹ kọ orin ìyìn; Ẹ kọ orin ìyìn sí Ọba wa, ẹ kọ orin ìyìn! 7 Nítorí Ọlọrun ni Ọba gbogbo ayé; Ẹ fi gbogbo ohun èlò ìkọrin kọ orin ìyìn! 8 Ọlọrun jọba lórí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; Ó gúnwà lórí ìtẹ́ mímọ́ rẹ̀. 9 Àwọn ìjòyè orílẹ̀-èdè kó ara wọn jọ pẹlu àwọn eniyan Ọlọrun Abrahamu. Ọlọrun ni aláṣẹ gbogbo ayé; òun ni ọlọ́lá jùlọ! |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria