O. Daf 46 - Yoruba BibleỌlọrun Wà pẹlu Wa 1 Ọlọrun ni ààbò ati agbára wa, olùrànlọ́wọ́ tí ó wà nítòsí nígbà gbogbo, ní ìgbà ìpọ́njú. 2 Nítorí náà ẹ̀rù kò ní bà wá bí ayé tilẹ̀ ṣídìí, bí àwọn òkè ńlá tilẹ̀ ṣípò pada, tí wọ́n bọ́ sinu òkun; 3 bí omi òkun tilẹ̀ ń hó, tí ó sì ń ru, tí àwọn òkè ńlá sì ń mì tìtì nítorí agbára ríru rẹ̀. 4 Odò kan wà tí omi rẹ̀ ń mú inú ìlú Ọlọrun dùn, ìlú yìí ni ibùgbé mímọ́ Ọ̀gá Ògo. 5 Ọlọrun wà láàrin rẹ̀, kò ní tú bẹ́ẹ̀ ni kò ní ṣí kúrò; Ọlọrun yóo ràn án lọ́wọ́ ní òwúrọ̀ kutukutu. 6 Inú àwọn orílẹ̀-èdè ń ru, àwọn ìjọba ayé ń gbọ̀n; OLUWA fọhùn, ayé sì yọ́. 7 OLUWA àwọn ọmọ ogun wà pẹlu wa; Ọlọrun Jakọbu ni ààbò wa. 8 Ẹ wá wo iṣẹ́ OLUWA, irú iṣẹ́ ribiribi tí ó ṣe láyé. 9 Ó dáwọ́ ogun dúró ní gbogbo ayé, ó ṣẹ́ ọrun, ó rún ọ̀kọ̀, ó dáná sun kẹ̀kẹ́ ogun. 10 “Ẹ dúró jẹ́ẹ́, kí ẹ sì mọ̀ pé èmi ni Ọlọrun. A gbé mi ga láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, a gbé mi ga ní ayé.” 11 OLUWA àwọn ọmọ ogun wà pẹlu wa, Ọlọrun Jakọbu ni ààbò wa. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria