O. Daf 43 - Yoruba BibleAdura Ẹni tí A Lé ní Ìlú 1 Dá mi láre, Ọlọrun, kí o sì gbèjà mi, lọ́dọ̀ àwọn tí kò mọ̀ Ọ́; gbà mí lọ́wọ́ àwọn ẹlẹ́tàn ati alaiṣootọ. 2 Nítorí ìwọ ni Ọlọrun tí mo sá di. Kí ló dé tí o fi ta mí nù? Kí ló dé tí mo fi ń ṣọ̀fọ̀ kiri nítorí ìnilára ọ̀tá? 3 Rán ìmọ́lẹ̀ rẹ ati òtítọ́ rẹ jáde, jẹ́ kí wọ́n máa tọ́ mi sọ́nà; jẹ́ kí wọ́n mú mi wá sí orí òkè mímọ́ rẹ, ati ibùgbé rẹ. 4 Nígbà náà ni n óo lọ sí ibi pẹpẹ Ọlọrun, àní, sọ́dọ̀ Ọlọrun, ayọ̀ ńlá mi. Èmi óo sì yìn ọ́ pẹlu hapu, Ọlọrun, Ọlọrun mi. 5 Ìwọ ọkàn mi, kí ló dé tí o fi rẹ̀wẹ̀sì? Kí ló dé tí ara rẹ kò fi balẹ̀ ninu mi? Gbẹ́kẹ̀ rẹ lé Ọlọrun; nítorí pé n óo tún yìn ín, olùrànlọ́wọ́ mi ati Ọlọrun mi. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria