Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

O. Daf 42 - Yoruba Bible


Adura Ẹni tí A Lé ní Ìlú

1 Bí ọkàn àgbọ̀nrín tií máa fà sí odò tí omi rẹ̀ tutù, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mi ń fà sí ọ, Ọlọrun.

2 Òùngbẹ Ọlọrun ń gbẹ ọkàn mi, àní, òùngbẹ Ọlọrun alààyè. Nígbà wo ni n óo lọ, tí n óo tún bá Ọlọrun pàdé?

3 Omijé ni mo fi ń ṣe oúnjẹ jẹ tọ̀sán-tòru, nígbà tí wọn ń bi mí lemọ́lemọ́ pé, “Níbo ni Ọlọrun rẹ wà?”

4 Àwọn nǹkan wọnyi ni mò ń ranti, bí mo ti ń tú ẹ̀dùn ọkàn mi jáde: bí mo ṣe máa ń bá ogunlọ́gọ̀ eniyan rìn, tí mò ń ṣáájú wọn, bí a bá ti ń rìn lọ́wọ̀ọ̀wọ́ lọ sí ilé Ọlọrun; pẹlu ìhó ayọ̀ ati orin ọpẹ́, láàrin ogunlọ́gọ̀ eniyan tí ń ṣe àjọ̀dún.

5 Ìwọ ọkàn mi, kí ló dé tí o fi rẹ̀wẹ̀sì? Kí ló dé tí ara rẹ kò fi balẹ̀ ninu mi? Gbẹ́kẹ̀ rẹ lé Ọlọrun, nítorí pé n óo tún yìn ín, olùrànlọ́wọ́ mi ati Ọlọrun mi.

6 Ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọkàn mi, nítorí náà mo ranti rẹ láti òkè Herimoni, ati láti òkè Misari, wá sí agbègbè odò Jọdani,

7 ìbànújẹ́ ń já lura wọn, ìdààmú sì ń dà gììrì, wọ́n bò mí mọ́lẹ̀ bí ìgbì omi òkun.

8 Ní ọ̀sán, OLUWA fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn, ní òru, orin rẹ̀ gba ẹnu mi, àní, adura sí Ọlọrun ìyè mi.

9 Mo bi Ọlọrun, àpáta mi pé, “Kí ló dé tí o fi gbàgbé mi? Kí ló dé tí mò ń ṣọ̀fọ̀ kiri nítorí ìnilára ọ̀tá?”

10 Bí ọgbẹ́ aṣekúpani ni ẹ̀gàn àwọn ọ̀tá mi rí lára mi, nígbà tí wọn ń bi mí lemọ́lemọ́ pé, “Níbo ni Ọlọrun rẹ wà?”

11 Ìwọ ọkàn mi, kí ló dé tí o fi ń rẹ̀wẹ̀sì? Kí ló dé tí ara rẹ kò fi balẹ̀ ninu mi? Gbẹ́kẹ̀ rẹ lé Ọlọrun; nítorí pé n óo tún yìn ín, olùrànlọ́wọ́ mi ati Ọlọrun mi.

Bible Society of Nigeria © 1900/2010

Bible Society of Nigeria
Lean sinn:



Sanasan