O. Daf 41 - Yoruba BibleAdura Ẹni tí ń Ṣàìsàn 1 Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ń ro ti àwọn aláìní: OLUWA yóo gbà á ní ọjọ́ ìpọ́njú. 2 OLUWA yóo máa ṣọ́ ọ, yóo sì dá a sí. Yóo ní ayọ̀ ní ilẹ̀ náà; OLUWA kò ní fi í lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́. 3 Nígbà tí ó bá wà ní ìdùbúlẹ̀ àìsàn, OLUWA yóo fún un lókun; ní àkókò àìlera OLUWA yóo wo gbogbo àrùn rẹ̀ sàn. 4 Mo ní, “OLUWA, ṣàánú mi kí o sì wò mí sàn; mo ti ṣẹ̀ ọ́.” 5 Àwọn ọ̀tá mi ń ro ibi sí mi, wọ́n ń wí pé, “Nígbà wo ni yóo kú, tí orúkọ rẹ̀ yóo parẹ́?” 6 Tí ọ̀kan bá wá bẹ̀ mí wò, ọ̀rọ̀ tí kò lórí, tí kò nídìí ni yóo máa sọ; bẹ́ẹ̀ ni ninu ọkàn rẹ̀, èrò ibi ni yóo máa gbà. Nígbà tí ó bá jáde, yóo máa rò mí kiri. 7 Gbogbo àwọn tí ó kórìíra mi jọ ń sọ̀rọ̀ wújẹ́wújẹ́ nípa mi; ohun tó burú jùlọ ni wọ́n ń rò sí mi. 8 Wọ́n ń wí pé, “Àìsàn burúkú ti gbé e dálẹ̀; kò ní dìde mọ́ níbi tí ó dùbúlẹ̀ sí.” 9 Àní ọ̀rẹ́ kòríkòsùn mi tí mo gbẹ́kẹ̀lé, tí ó ń jẹun nílé mi, ó ti kẹ̀yìn sí mí. 10 Ṣugbọn, OLUWA, ṣàánú mi; gbé mi dìde, kí n lè san ẹ̀san fún un. 11 Kí n lè mọ̀ pé o fẹ́ràn mi, nígbà tí ọ̀tá kò bá borí mi. 12 O ti gbé mi ró nítorí ìwà pípé mi, o sì fi ẹsẹ̀ mi múlẹ̀ níwájú rẹ títí lae. 13 Ìyìn ni fún OLUWA, Ọlọrun Israẹli, lae ati laelae. Amin! Amin! |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria