O. Daf 40 - Yoruba BibleOrin ìyìn 1 Sùúrù ni mo fi dúró de OLUWA, ó dẹ etí sí mi, ó sì gbọ́ igbe mi. 2 Ó fà mí jáde láti inú ọ̀gbun ìparun, láti inú kòtò tí ó kún fún ẹrọ̀fọ̀; ó gbé mi kalẹ̀ lórí àpáta, ó sì fi ẹsẹ̀ mi tẹlẹ̀. 3 Ó fi orin titun sí mi lẹ́nu, àní, orin ìyìn sí Ọlọrun wa. Ọ̀pọ̀ yóo rí i, ẹ̀rù óo bà wọ́n, wọn óo sì gbẹ́kẹ̀lé OLUWA. 4 Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni náà, tí ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé OLUWA, tí kò bá àwọn onigbeeraga rìn, àwọn tí wọn ti ṣìnà lọ sọ́dọ̀ àwọn oriṣa. 5 OLUWA, Ọlọrun mi, o ti ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu fún wa, o sì ti ro ọ̀pọ̀ èrò rere kàn wá. Kò sí ẹni tí a lè fi wé ọ; bí mo bá ní kí n máa polongo ohun tí o ṣe, kí n máa ròyìn wọn, wọ́n ju ohun tí eniyan lè kà lọ. 6 O ò fẹ́ ẹbọ, bẹ́ẹ̀ ni o ò fẹ́ ọrẹ, ṣugbọn o là mí ní etí; o ò bèèrè ẹbọ sísun tabi ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. 7 Nígbà náà ni mo wí pé, “Wò ó, mo dé; a ti kọ nípa mi sinu ìwé pé: 8 mo gbádùn láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọrun mi; mo sì ń pa òfin rẹ mọ́ ninu ọkàn mi.” 9 Mo ti ròyìn òdodo ninu àwùjọ ńlá. Wò ó, OLUWA n kò pa ẹnu mi mọ́, gẹ́gẹ́ bí o ti mọ̀. 10 Èmi kò fi ìròyìn ìrànlọ́wọ́ ìgbàlà rẹ pamọ́. Mo sọ̀rọ̀ òtítọ́ ati ìgbàlà rẹ; n kò dákẹ́ lẹ́nu nípa òtítọ́ ati ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, ninu àwùjọ ńlá. 11 Má dáwọ́ àánú rẹ dúró lórí mi, OLUWA, sì jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́ rẹ máa pa mí mọ́. Adura Ìrànlọ́wọ́ 12 Nítorí pé àìmọye ìdààmú ló yí mi ká, ọwọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi ti tẹ̀ mí, tóbẹ́ẹ̀ tí n kò ríran. Wọ́n pọ̀ ju irun orí mi lọ, ọkàn mi ti dàrú. 13 OLUWA, dákun gbà mi; yára, OLUWA, ràn mí lọ́wọ́. 14 Jẹ́ kí ojú ti gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ gba ẹ̀mí mi, kí ìdàrúdàpọ̀ bá gbogbo wọn patapata, jẹ́ kí á lé àwọn tí ń wá ìpalára mi pada sẹ́yìn, kí wọ́n sì tẹ́. 15 Jẹ́ kí jìnnìjìnnì bò wọ́n, kí wọ́n sì gba èrè ìtìjú, àní, àwọn tí ń ṣe jàgínní mi. 16 Kí gbogbo àwọn tí ń wá ọ máa yọ̀, kí inú wọn sì máa dùn nítorí rẹ; kí àwọn tí ó fẹ́ràn ìgbàlà rẹ máa wí nígbà gbogbo pé, “OLUWA tóbi!” 17 Ní tèmi, olùpọ́njú ati aláìní ni mí; ṣugbọn Oluwa kò gbàgbé mi. Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ ati olùgbàlà mi, má pẹ́, Ọlọrun mi. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria