Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

O. Daf 39 - Yoruba Bible


Ìráhùn Ẹni tí Ìyà ń Jẹ

1 Mo ní, “Èmi óo máa ṣọ́ra, kí n má baà fi ahọ́n mi dẹ́ṣẹ̀; n óo kó ẹnu mi ní ìjánu, níwọ̀n ìgbà tí àwọn eniyan burúkú bá wà nítòsí.”

2 Mo dákẹ́, n ò sọ nǹkankan; n ò tilẹ̀ dá sí ọ̀rọ̀ rere pàápàá; sibẹ ìpọ́njú mi ń pọ̀ sí i

3 ìdààmú dé bá ọkàn mi. Bí mo ti ń ronú, ọkàn mi dàrú; mo bá sọ̀rọ̀ jáde, mo ní:

4 “OLUWA, jẹ́ kí n mọ òpin ayé mi, ati ìwọ̀nba ọjọ́ ayé mi, kí n lè mọ̀ pé ayé mi ń sáré kọjá lọ.”

5 Wò ó, o ti ṣe ọjọ́ mi ní ìwọ̀n ìbú àtẹ́lẹwọ́ mélòó kan, ọjọ́ ayé mi kò sì tó nǹkankan ní ojú rẹ; dájúdájú, ọmọ eniyan dàbí afẹ́fẹ́ lásán.

6 Dájúdájú, eniyan ń káàkiri bí òjìji, asán sì ni gbogbo làálàá rẹ̀; eniyan a máa kó ọrọ̀ jọ ṣá, láìmọ ẹni tí yóo kó o lọ.

7 Wàyí ò, OLUWA, kí ló kù tí mo gbójú lé? Ìwọ ni mo fẹ̀yìn tì.

8 Gbà mí ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ìrékọjá mi; má sọ mí di ẹni ẹ̀gàn lójú àwọn òmùgọ̀.

9 Mo dákẹ́, n kò ya ẹnu mi; nítorí pé ìwọ ni o ṣe é.

10 Dáwọ́ ẹgba rẹ dúró lára mi, mo ti fẹ́rẹ̀ kú nítorí ìyà tí o fi ń jẹ mí.

11 Nígbà tí o bá jẹ eniyan níyà pẹlu ìbáwí nítorí ẹ̀ṣẹ̀, ìwọ á ba ohun tí ó ṣọ̀wọ́n fún un jẹ́ bíi kòkòrò aṣọ. Dájúdájú, afẹ́fẹ́ lásán ni eniyan.

12 “OLUWA, gbọ́ adura mi, tẹ́tí sí igbe mi, má dágunlá sí ẹkún mi, nítorí pé àlejò rẹ, tí ń rékọjá lọ ni mo jẹ́; àjèjì sì ni mí, bíi gbogbo àwọn baba mi.

13 Mú ojú ìbáwí kúrò lára mi, kí inú mi lè dùn kí n tó kọjá lọ; àní, kí n tó ṣe aláìsí.”

Bible Society of Nigeria © 1900/2010

Bible Society of Nigeria
Lean sinn:



Sanasan