O. Daf 36 - Yoruba BibleÌwà ìkà 1 Ẹ̀ṣẹ̀ ń gbin lọ́kàn eniyan burúkú, kò sí ìbẹ̀rù Ọlọrun ninu èrò tirẹ̀. 2 Nítorí pé lọ́kàn rẹ̀ a máa pọ́n ara rẹ̀, pé kò sí ẹni tí ó lè rí ẹ̀ṣẹ̀ òun, ká tó wá sọ pé yóo dá òun lẹ́bi. 3 Ọ̀rọ̀ ìkà ati ẹ̀tàn ni ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀. Ó ti dáwọ́ ire ṣíṣe dúró; kò sì hu ìwà ọlọ́gbọ́n mọ́. 4 A máa pète ìkà lórí ibùsùn rẹ̀; a máa rin ọ̀nà tí kò tọ́; kò sì kórìíra ibi. Oore Ọlọrun 5 OLUWA, ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ga kan ọ̀run; òtítọ́ rẹ sì kan ojú ọ̀run. 6 Òtítọ́ rẹ dàbí òkè ńlá; ìdájọ́ rẹ sì jìn bí ibú omi. OLUWA, àtènìyàn, àtẹranko ni ò ń gbàlà. 7 Ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ níye lórí pupọ, Ọlọrun! Àwọn ọmọ eniyan a máa sá sí abẹ́ òjìji ìyẹ́ apá rẹ. 8 Wọ́n ń rí oúnjẹ jẹ ní àjẹyó ní ilé rẹ; nǹkan mímu tí ń ṣàn bí odò, ni o sì ń fún wọn mu. 9 Nítorí pé lọ́dọ̀ rẹ ni orísun ìyè wà; ninu ìmọ́lẹ̀ rẹ ni a ti ń rí ìmọ́lẹ̀. 10 Túbọ̀ máa fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ han àwọn tí ó mọ̀ ọ́, sì máa fi òdodo rẹ han àwọn ọlọ́kàn mímọ́. 11 Má jẹ́ kí àwọn agbéraga borí mi, má sì jẹ́ kí àwọn eniyan burúkú lé mi kúrò. 12 Ẹ wo àwọn aṣebi níbi tí wọ́n ṣubú sí; wọ́n dà wólẹ̀, wọn kò sì le dìde. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria