O. Daf 34 - Yoruba BibleẸ yin Ọlọrun nítorí Oore Rẹ̀ 1 N óo máa yin OLUWA ní gbogbo ìgbà; ìyìn rẹ̀ yóo máa wà ní ẹnu mi nígbà gbogbo. 2 OLUWA ni èmi óo máa fi yangàn; kí inú àwọn olùpọ́njú máa dùn nígbà tí wọ́n bá gbọ́. 3 Ẹ bá mi gbé OLUWA ga, ẹ jẹ́ kí á jùmọ̀ gbé orúkọ rẹ̀ lékè! 4 Mo ké pe OLUWA, ó sì dá mi lóhùn, ó sì gbà mí lọ́wọ́ gbogbo ohun tí ń bà mí lẹ́rù. 5 Wọ́n gbójú sókè sí OLUWA, wọ́n láyọ̀; ojú kò sì tì wọ́n. 6 Olùpọ́njú ké pe OLUWA, OLUWA gbọ́ ohùn rẹ̀, ó sì gbà á ninu gbogbo ìpọ́njú rẹ̀. 7 Angẹli OLUWA yí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ká, a sì máa gbà wọ́n. 8 Tọ́ ọ wò, kí o sì rí i pé rere ni OLUWA! Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá sá di í! 9 Ẹ bẹ̀rù OLUWA, ẹ̀yin eniyan mímọ́ rẹ̀, nítorí pé kò sí àìní fún àwọn tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀! 10 Àwọn ọmọ kinniun a máa ṣe aláìní, ebi a sì máa pa wọ́n; ṣugbọn àwọn tí wọ́n bá ń wá OLUWA kò ní ṣe aláìní ohun rere kankan. 11 Ẹ wá, ẹ̀yin ọmọ, ẹ tẹ́tí sí mi, n óo kọ yín ní ìbẹ̀rù OLUWA. 12 Ta ni ń fẹ́ ìyè ninu yín, tí ń fẹ́ ẹ̀mí gígùn, tí ó fẹ́ pẹ́ láyé? 13 Ẹ ṣọ́ ẹnu yín, ẹ má sọ̀rọ̀ burúkú, ẹ má sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ti ẹnu yín jáde. 14 Ẹ yàgò fún ibi, rere ni kí ẹ máa ṣe; ẹ máa wá alaafia, kí ẹ sì máa lépa rẹ̀. 15 OLUWA ń ṣọ́ àwọn olódodo, Ó sì ń dẹ etí sí igbe wọn. 16 OLUWA fojú sí àwọn aṣebi lára, láti pa wọ́n rẹ́, kí á má sì ṣe ranti wọn mọ́ lórí ilẹ̀ ayé. 17 Nígbà tí olódodo bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́, OLUWA a máa gbọ́, a sì máa gbà wọ́n kúrò ninu gbogbo ìyọnu wọn. 18 OLUWA wà nítòsí àwọn tí ọkàn wọn bàjẹ́, a sì máa gba àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn là. 19 Ìpọ́njú olódodo a máa pọ̀; ṣugbọn OLUWA a máa kó o yọ ninu gbogbo wọn. 20 A máa pa gbogbo egungun rẹ̀ mọ́; kì í jẹ́ kí ọ̀kankan fọ́ ninu wọn. 21 Ibi ni yóo pa eniyan burúkú; a óo sì dá àwọn tí ó kórìíra olódodo lẹ́bi. 22 OLUWA ra ẹ̀mí àwọn iranṣẹ rẹ̀ pada; ẹnikẹ́ni tí ó bá sá di í kò ní jẹ̀bi. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria