O. Daf 32 - Yoruba BibleÌjẹ́wọ́ Ẹ̀ṣẹ̀ 1 Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí a dárí ìrékọjá rẹ̀ jì, tí a bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀. 2 Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí OLUWA kò ka ẹ̀ṣẹ̀ sí lọ́rùn, tí ẹ̀tàn kò sì sí ninu ọkàn rẹ̀. 3 Nígbà tí n kò jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi, ó rẹ̀ mí wá láti inú, nítorí kíkérora tí mò ń kérora ní gbogbo ìgbà. 4 Nítorí tọ̀sán-tòru ni o fi ń jẹ mí níyà; gbogbo agbára mi ló lọ háú, bí omi tíí gbẹ lákòókò ẹ̀ẹ̀rùn. 5 Mo jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi fún ọ; n kò sì fi àìdára mi pamọ́ fún ọ. Mo ní, “Èmi óo jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi fún Oluwa,” o sì dáríjì mí. 6 Nítorí náà, kí gbogbo olódodo máa gbadura sí ọ; ní àkókò tí ìpọ́njú bá ń yí lura wọn bí ìṣàn omi ńlá, kò ní dé ọ̀dọ̀ wọn. 7 Ìwọ ni ibi ìsásí mi; o pa mí mọ́ kúrò ninu ìṣòro; o sì fi ìgbàlà yí mi ká. 8 N óo kọ́ ọ, n óo sì tọ́ ọ sí ọ̀nà tí o óo rìn; n óo máa gbà ọ́ ní ìmọ̀ràn; n óo sì máa mójútó ọ. 9 Má ṣe dàbí ẹṣin tabi ìbaaka, tí kò ni ọgbọ́n ninu, tí a gbọdọ̀ kó ìjánu sí lẹ́nu kí ó tó lè gbọ́ ti oluwa rẹ̀. 10 Ìrora pọ̀ fún àwọn eniyan burúkú, ṣugbọn ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ni ó yí àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWA ká. 11 Ẹ máa yọ̀ ninu OLUWA; ẹ fò fún ayọ̀, ẹ̀yin olódodo; kí ẹ sì hó fún ayọ̀, gbogbo ẹ̀yin ọlọ́kàn mímọ́. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria