Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

O. Daf 30 - Yoruba Bible


Adura Ọpẹ́

1 N óo yìn ọ́, OLUWA, nítorí pé o ti yọ mí jáde; o kò sì jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi ó yọ̀ mí.

2 OLUWA, Ọlọrun mi, mo ké pè ọ́, o sì wò mí sàn.

3 OLUWA, o ti yọ mí kúrò ninu isà òkú o sọ mí di ààyè láàrin àwọn tí wọ́n ti wọ inú kòtò.

4 Ẹ kọ orin ìyìn sí OLUWA, ẹ̀yin olùfọkànsìn rẹ̀, kí ẹ sì fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ̀.

5 Nítorí pé fún ìgbà díẹ̀ ni ibinu rẹ̀, ṣugbọn títí ayé ni ojurere rẹ̀; eniyan lè máa sọkún títí di alẹ́, ṣugbọn ayọ̀ ń bọ̀ fún un lówùúrọ̀.

6 Nígbà tí ara rọ̀ mí, mo wí ninu ọkàn mi pé, kò sí ohun tí ó lè mì mí laelae.

7 Nípa ojurere rẹ, OLUWA, o ti fi ìdí mi múlẹ̀ bí òkè ńlá; ṣugbọn nígbà tí o fi ojú pamọ́ fún mi, ìdààmú dé bá mi.

8 Ìwọ ni mò ń ké pè, OLUWA, OLUWA, ìwọ ni mò ń bẹ̀.

9 Anfaani wo ló wà ninu pé kí n kú? Èrè wo ló wà ninu pé kí n wọ inú kòtò? Ṣé erùpẹ̀ lè yìn ọ́? Ṣé ó lè sọ nípa òdodo rẹ?

10 Gbọ́ OLUWA, kí o sì ṣàánú mi, OLUWA, ràn mí lọ́wọ́.

11 O ti bá mi sọ ọ̀fọ̀ mi di ijó, o ti bọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ kúrò lára mi, o sì ti dì mí ní àmùrè ayọ̀,

12 kí ọkàn mi lè máa yìn ọ́ láìdákẹ́. OLUWA Ọlọrun mi, n óo máa fi ọpẹ́ fún ọ títí lae.

Bible Society of Nigeria © 1900/2010

Bible Society of Nigeria
Lean sinn:



Sanasan