O. Daf 3 - Yoruba BibleAdura ìrànlọ́wọ́ lówùúrọ̀ 1 OLUWA, àwọn ọ̀tá mi pọ̀ pupọ! Ọ̀pọ̀ ni ó ń dìde sí mi! 2 Ọpọlọpọ ni àwọn tí ń sọ kiri pé, Ọlọrun kò ní gbà mí sílẹ̀! 3 Ṣugbọn ìwọ OLUWA ni ààbò mi, ògo mi, ati ẹni tí ó fún mi ní ìgboyà. 4 Mo ké pe OLUWA, ó sì dá mi lóhùn láti òkè mímọ́ rẹ̀ wá. 5 Mo dùbúlẹ̀, mo sùn, mo sì jí, nítorí OLUWA ni ó ń gbé mi ró. 6 Ẹgbẹẹgbẹrun ọ̀tá tó yí mi ká kò le bà mí lẹ́rù. 7 Dìde, OLUWA, gbà mí, Ọlọrun mi! Nítorí ìwọ ni o lu gbogbo àwọn ọ̀tá mi bolẹ̀, tí o sì ṣẹgun àwọn eniyan burúkú. 8 OLUWA níí gbani, kí ibukun rẹ̀ kí ó wà lórí àwọn eniyan rẹ̀. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria