O. Daf 29 - Yoruba BibleAgbára OLUWA ninu ìjì 1 Ẹ̀yin ẹ̀dá ọ̀run, ẹ fi ògo fún OLUWA, ẹ gbé agbára rẹ̀ lárugẹ. 2 Ẹ fún OLUWA ní ògo tí ó yẹ orúkọ rẹ̀, ẹ máa sin OLUWA ninu ẹwà mímọ́ rẹ̀. 3 À ń gbọ́ ohùn OLUWA lójú omi òkun, Ọlọrun ológo ń sán ààrá, Ọlọrun ń sán ààrá lójú alagbalúgbú omi. 4 Ohùn OLUWA lágbára, ohùn OLUWA kún fún ọlá ńlá. 5 Ohùn OLUWA ń fọ́ igi kedari, OLUWA ń fọ́ igi kedari ti Lẹbanoni. 6 Ó ń mú kí òkè Lẹbanoni ta pọ́núnpọ́nún bí ọmọ mààlúù, ó sì mú kí òkè Sirioni máa fò bí akọ ọmọ mààlúù-igbó. 7 Ohùn OLUWA ń yọ iná lálá. 8 Ohùn OLUWA ń mi aṣálẹ̀; OLUWA ń mi aṣálẹ̀ Kadeṣi. 9 Ohùn OLUWA a máa mú abo àgbọ̀nrín bí, a máa wọ́ ewé lára igi oko; gbogbo eniyan ń kígbe ògo rẹ̀ ninu Tẹmpili rẹ̀. 10 OLUWA jókòó, ó gúnwà lórí ìkún omi; OLUWA jókòó, ó gúnwà bí ọba títí lae. 11 OLUWA yóo fún àwọn eniyan rẹ̀ ní agbára; OLUWA yóo fún wọn ní ibukun alaafia. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria