Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

O. Daf 28 - Yoruba Bible


Adura Ìrànlọ́wọ́

1 Ìwọ ni mo kígbe pè, OLUWA, ìwọ ni ààbò mi, má di etí sí mi. Nítorí bí o bá dákẹ́ sí mi n óo dàbí àwọn òkú, tí wọ́n ti lọ sinu kòtò.

2 Gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi, bí mo ti ń kígbe sí ọ pé kí o ràn mí lọ́wọ́; tí mo gbé ọwọ́ mi sókè sí ìhà ilé mímọ́ rẹ.

3 Má ṣe kó mi lọ pẹlu àwọn eniyan burúkú, pẹlu àwọn tí ń ṣe iṣẹ́ ibi, àwọn tí ń bá àwọn aládùúgbò wọn sọ ọ̀rọ̀ alaafia, ṣugbọn tí ètekéte ń bẹ ninu ọkàn wọn.

4 San án fún wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn, àní gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ burúkú wọn; san án fún wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn, fún wọn ní èrè tí ó tọ́ sí wọn.

5 Nítorí pé wọn kò ka iṣẹ́ OLUWA sí, wọn kò sì bìkítà fún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, OLUWA yóo sọ wọ́n di ilẹ̀, kò sì ní gbé wọn dìde mọ́.

6 Ẹni ìyìn ni OLUWA! Nítorí pé ó ti gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.

7 OLUWA ni agbára ati asà mi, òun ni mo gbẹ́kẹ̀lé; ó ràn mí lọ́wọ́, ọkàn mi sì kún fún ayọ̀; mo sì fi orin ìyìn dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀.

8 OLUWA ni agbára àwọn eniyan rẹ̀; òun ni ààbò ìgbàlà fún ẹni àmì òróró rẹ̀.

9 Gba àwọn eniyan rẹ là, OLUWA, kí o sì bukun ilẹ̀ ìní rẹ. Jẹ́ olùṣọ́-aguntan wọn, kí o sì máa tọ́jú wọn títí lae.

Bible Society of Nigeria © 1900/2010

Bible Society of Nigeria
Lean sinn:



Sanasan