O. Daf 24 - Yoruba BibleỌba Atóbijù 1 OLUWA ló ni ilẹ̀ ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀, òun ló ni ayé, ati gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀; 2 nítorí pé òun ló fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ lórí òkun, ó sì gbé e kalẹ̀ lórí ìṣàn omi. 3 Ta ló lè gun orí òkè OLUWA lọ? Ta ló sì lè dúró ninu ibi mímọ́ rẹ̀? 4 Ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ mọ́, tí inú rẹ̀ sì funfun, tí kò gbẹ́kẹ̀lé oriṣa lásánlàsàn, tí kò sì búra èké. 5 Òun ni yóo rí ibukun gbà lọ́dọ̀ OLUWA, tí yóo sì rí ìdáláre gbà lọ́wọ́ Ọlọrun, Olùgbàlà rẹ̀. 6 Irú wọn ni àwọn tí ń wá OLUWA, àní àwọn tí ń wá ojurere Ọlọrun Jakọbu. 7 Ẹ ṣí sílẹ̀ gbayau, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn, ẹ wà ní ṣíṣí sílẹ̀, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn ayérayé, kí Ọba ògo lè wọlé. 8 Ta ni Ọba ògo yìí? OLUWA tí ó ní ipá tí ó sì lágbára, OLUWA tí ó lágbára lógun. 9 Ẹ ṣí sílẹ̀ gbayau, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn, ẹ wà ní ṣíṣí sílẹ̀, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn ayérayé, kí Ọba ògo lè wọlé. 10 Ta ni Ọba ògo yìí? OLUWA àwọn ọmọ ogun, òun ni Ọba ògo náà. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria