Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

O. Daf 23 - Yoruba Bible


OLUWA ni Olùṣọ́ Mi

1 OLUWA ni Olùṣọ́-aguntan mi, n kò ní ṣe àìní ohunkohun.

2 Ó mú mi dùbúlẹ̀ ninu pápá koríko tútù, ó mú mi lọ sí ibi tí omi ti dákẹ́ rọ́rọ́;

3 ó sọ agbára mi dọ̀tun. Ó tọ́ mi sí ọ̀nà òdodo nítorí orúkọ rẹ̀.

4 Àní, bí mo tilẹ̀ ń rìn ninu òkùnkùn létí bèbè ikú, n kò ní bẹ̀rù ibi kankan; nítorí tí o wà pẹlu mi; ọ̀gọ rẹ ati ọ̀pá rẹ ń fi mí lọ́kàn balẹ̀.

5 O gbé oúnjẹ kalẹ̀ níwájú mi, níṣojú àwọn ọ̀tá mi; o da òróró sí mi lórí; o sì bu ife mi kún ní àkúnwọ́sílẹ̀.

6 Dájúdájú, ire ati àánú yóo máa tẹ̀lé mi kiri, ní gbogbo ọjọ́ ayé mi; èmi óo sì máa gbé inú ilé OLUWA laelae.

Bible Society of Nigeria © 1900/2010

Bible Society of Nigeria
Lean sinn:



Sanasan