O. Daf 21 - Yoruba BibleOrin Ìṣẹ́gun 1 Ọba ń yọ̀ nítorí agbára rẹ, OLUWA; inú rẹ̀ ń dùn lọpọlọpọ nítorí ríràn tí o ràn án lọ́wọ́! 2 O ti fún un ní ohun tí ọkàn rẹ̀ ń fẹ́, o kò sì fi ohun tí ó ń tọrọ dù ú. 3 O gbé ibukun dáradára pàdé rẹ̀; o fi adé ojúlówó wúrà dé e lórí. 4 Ó bèèrè ẹ̀mí gígùn lọ́wọ́ rẹ; o fi fún un, àní, ọjọ́ gbọọrọ títí ayé. 5 Òkìkí rẹ̀ pọ̀ nítorí pé o ràn án lọ́wọ́; o sì fi iyì ati ọlá ńlá jíǹkí rẹ̀. 6 Nítòótọ́ o sọ ọ́ di ẹni ibukun títí lae; o sì mú kí inú rẹ̀ dùn nítorí pé o wà pẹlu rẹ̀. 7 Nítorí pé ọba gbẹ́kẹ̀lé OLUWA; a kò ní ṣí i ní ipò pada, nítorí ìfẹ́ Ọ̀gá Ògo tí kì í yẹ̀. 8 Ọwọ́ rẹ yóo tẹ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ; ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóo tẹ gbogbo àwọn tí ó kórìíra rẹ. 9 O óo jó wọn run bí iná ìléru, nígbà tí o bá yọ sí wọn. OLUWA yóo gbé wọn mì ninu ibinu rẹ̀; iná yóo sì jó wọn ní àjórun. 10 O óo pa àwọn ọmọ wọn run lórí ilẹ̀ ayé, o óo sì run ìran wọn láàrin àwọn eniyan. 11 Bí wọn bá gbèrò ibi sí ọ, tí wọ́n sì pète ìkà, wọn kò ní lè ṣe é. 12 Nítorí pé o óo lé wọn sá; nígbà tí o bá fi ọfà rẹ sun ojú wọn. 13 A gbé ọ ga, nítorí agbára rẹ, OLUWA! A óo máa kọrin, a óo sì máa yin agbára rẹ. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria