O. Daf 20 - Yoruba BibleAdura Ìṣẹ́gun 1 OLUWA óo dá ọ lóhùn ní ọjọ́ ìpọ́njú, orúkọ Ọlọrun Jakọbu óo dáàbò bò ọ́. 2 Yóo rán olùrànlọ́wọ́ sí ọ láti ilé mímọ́ rẹ̀ wá, yóo sì tì ọ́ lẹ́yìn láti Sioni wá. 3 Yóo ranti gbogbo ẹbọ ọrẹ rẹ, yóo sì gba ẹbọ sísun rẹ. 4 Yóo fún ọ ní ohun tí o fẹ́ ninu ọkàn rẹ, yóo sì mú gbogbo èrò rẹ ṣẹ. 5 Ìhó ayọ̀ ni a óo hó nígbà tí o bá ṣẹgun, ní orúkọ Ọlọrun wa ni a óo sì fi ọ̀págun wa sọlẹ̀; OLUWA yóo dáhùn gbogbo ìbéèrè rẹ. 6 Mo wá mọ̀ nisinsinyii pé OLUWA yóo ran ẹni àmì òróró rẹ̀ lọ́wọ́; OLUWA yóo dá a lóhùn láti ọ̀run mímọ́ rẹ̀ wá yóo sì fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ fún un ní ìṣẹ́gun ńlá. 7 Àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀lé kẹ̀kẹ́ ogun, àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀lé ẹṣin, ṣugbọn ní tiwa, àwa gbẹ́kẹ̀lé orúkọ OLUWA Ọlọrun wa. 8 Àwọn óo kọsẹ̀, wọn óo sì ṣubú, ṣugbọn àwa óo dìde, a óo sì dúró ṣinṣin. 9 Fún ọba ní ìṣẹ́gun, OLUWA; kí o sì dá wa lóhùn nígbà tí a bá ń ké pè ọ́. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria