O. Daf 2 - Yoruba BibleÀyànfẹ́ Ọlọrun 1 Kí ló dé tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń bínú fùfù tí àwọn eniyan ń gbìmọ̀ asán? 2 Àwọn ọba ayé kó ara wọn jọ, àwọn ìjòyè gbìmọ̀ pọ̀, wọ́n dojú kọ OLUWA ati àyànfẹ́ rẹ̀. 3 Wọn ń wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á fa ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi dè wá já kí á sì yọ ara wa kúrò lóko ẹrú wọn.” 4 Ẹni tí ó gúnwà lọ́run ń fi wọ́n rẹ́rìn-ín; OLUWA sì ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́. 5 Lẹ́yìn náà, yóo sọ̀rọ̀ sí wọn ninu ibinu rẹ̀, yóo dẹ́rùbà wọ́n gidigidi ninu ìrúnú rẹ̀, 6 Yóo wí pé, “Mo ti fi ọba mi jẹ, ní Sioni, lórí òkè mímọ́ mi.” 7 N óo kéde ohun tí OLUWA pa láṣẹ ní ti èmi ọba; Ó wí fún mi pé, “Ìwọ ni ọmọ mi, lónìí ni mo bí ọ. 8 Bèèrè lọ́wọ́ mi, èmi ó sì fún ọ ní àwọn orílẹ̀-èdè, gbogbo ayé yóo sì di tìrẹ. 9 Ìwọ óo fi ọ̀pá irin fọ́ wọn, o óo sì fọ́ wọn túútúú bí ìkòkò amọ̀.” 10 Nítorí náà, ẹ̀yin ọba, ẹ kọ́gbọ́n; ẹ̀yin onídàájọ́ ayé, ẹ gba ìkìlọ̀. 11 Ẹ fi ìbẹ̀rù sin OLUWA, ẹ yọ̀ pẹlu ìwárìrì. 12 Ẹ júbà ọmọ náà, kí ó má baà bínú, kí ó má baà pa yín run lójijì; nítorí a máa yára bínú. Ayọ̀ ń bẹ fún gbogbo àwọn tí ó wá ààbò lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria