O. Daf 19 - Yoruba BibleÒgo Ọlọrun ninu àwọn ohun tí Ó dá 1 Ojú ọ̀run ń sọ̀rọ̀ ògo Ọlọrun, òfuurufú sì ń kéde iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. 2 Ọjọ́ dé ọjọ́ ń sọ ọ́ ní àsọgbà òru dé òru sì ń fi ìmọ̀ rẹ̀ hàn. 3 Wọn kò fọ èdè kankan, wọn kò sì sọ ọ̀rọ̀; bẹ́ẹ̀ ni a kò gbọ́ ohùn wọn; 4 sibẹ ìró wọn la gbogbo ayé já, ọ̀rọ̀ wọn sì dé òpin ayé. Ó pàgọ́ fún oòrùn lójú ọ̀run, 5 tí ó ń yọ jáde bí ọkọ iyawo tí ń jáde láti inú yàrá rẹ̀, ati bí akọni tí ara ń wá láti fi tayọ̀tayọ̀ sáré ìje. 6 Láti apá kan ojú ọ̀run ni ó ti ń yọ wá, a máa yípo gbogbo ojú ọ̀run dé apá keji; kò sì sí ohun tí ó bọ́ lọ́wọ́ ooru rẹ̀. Òfin OLUWA 7 Òfin OLUWA pé, a máa sọ ọkàn jí; àṣẹ OLUWA dájú, ó ń sọ òpè di ọlọ́gbọ́n. 8 Ìlànà OLUWA tọ́, ó ń mú ọkàn yọ̀, àṣẹ OLUWA péye, a máa lani lójú. 9 Ìbẹ̀rù OLUWA pé, ó wà títí lae, ìdájọ́ OLUWA tọ́, òdodo ni gbogbo wọn. 10 Wọ́n wuni ju wúrà lọ, àní ju ojúlówó wúrà lọ; wọ́n sì dùn ju oyin, àní, wọ́n dùn ju oyin tí ń kán láti inú afárá lọ. 11 Pẹlupẹlu àwọn ni wọ́n ń ki èmi iranṣẹ rẹ, nílọ̀, èrè pupọ sì ń bẹ ninu pípa wọ́n mọ́. 12 Ṣugbọn ta ni lè mọ àṣìṣe ara rẹ̀? Wẹ̀ mí mọ́ ninu àṣìṣe àìmọ̀ mi. 13 Pa èmi iranṣẹ rẹ mọ́ kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀-ọ́n-mọ̀-dá; má jẹ́ kí wọ́n jọba lórí mi. Nígbà náà ni ara mi yóo mọ́, n kò sì ní jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ńlá. 14 Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹnu mi, ati àṣàrò ọkàn mi jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà ní ojú rẹ, OLUWA ibi ààbò mi ati olùràpadà mi. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria