O. Daf 16 - Yoruba BibleMo Sá di OLUWA 1 Pa mí mọ́ Ọlọrun, nítorí ìwọ ni mo sá di. 2 Mo wí fún ọ, OLUWA, pé, “Ìwọ ni Oluwa mi; ìwọ nìkan ni orísun ire mi.” 3 Nípa àwọn eniyan mímọ́ tí ó wà nílẹ̀ yìí, wọ́n jẹ́ ọlọ́lá tí àwọn eniyan fẹ́ràn. 4 “Ìbànújẹ́ àwọn tí ń sá tọ ọlọrun mìíràn lẹ́yìn yóo pọ̀: Èmi kò ní bá wọn ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ fún ìrúbọ, bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kò ní gbọ́ orúkọ wọn lẹ́nu mi.” 5 OLUWA, ìwọ ni ìpín mi, ìwọ ni mo yàn; ìwọ ni ò ń jẹ́ kí ọ̀ràn mi fìdí múlẹ̀. 6 Ìpín tí ó bọ́ sí mi lọ́wọ́ dára pupọ; ogún rere ni ogún ti mo jẹ. 7 Èmi óo máa yin OLUWA, ẹni tí ó ń fún mi ní òye; ọkàn mi ó sì máa tọ́ mi sọ́nà ní òròòru. 8 Mò ń wo OLUWA ní iwájú mi nígbà gbogbo, nítorí pé Ọlọrun dúró tì mí, ẹsẹ̀ mi kò ní yẹ̀. 9 Nítorí náà ni ọkàn mi ṣe ń yọ̀, tí inú mi dùn; ara sì rọ̀ mí. 10 Nítorí o kò ní gbàgbé mi sí ipò òkú, bẹ́ẹ̀ ni o kò ní jẹ́ kí ẹni tí ó fi tọkàntọkàn sìn ọ́ rí ìdíbàjẹ́. 11 O ti fi ọ̀nà ìyè hàn mí; ayọ̀ kíkún ń bẹ ní iwájú rẹ, ìgbádùn àìlópin sì ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria