O. Daf 150 - Yoruba BibleẸ yin OLUWA 1 Ẹ yin OLUWA! Ẹ yin Ọlọrun ninu ibi mímọ́ rẹ̀; ẹ yìn ín ninu òfuurufú rẹ̀ tí ó lágbára. 2 Ẹ yìn ín fún iṣẹ́ ńlá rẹ̀; ẹ yìn ín nítorí pé ó tóbi pupọ. 3 Ẹ fi ariwo fèrè yìn ín; ẹ fi fèrè ati hapu yìn ín. 4 Ẹ fi ìlù ati ijó yìn ín; ẹ fi gòjé ati dùùrù yìn ín. 5 Ẹ fi aro olóhùn òkè yìn ín; ẹ fi aro olóhùn gooro yìn ín. 6 Kí gbogbo nǹkan ẹlẹ́mìí yin OLUWA! Ẹ yin OLUWA! |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria