O. Daf 15 - Yoruba BibleÌwà tí Ọlọrun Fẹ́ 1 OLUWA, ta ni ó lè máa gbé inú àgọ́ rẹ? Ta ni ó lè máa gbé orí òkè mímọ́ rẹ? 2 Ẹni tí ń rìn déédéé, tí ń ṣe òdodo; tí sì ń fi tọkàntọkàn sọ òtítọ́. 3 Ẹni tí kò fi ahọ́n rẹ̀ sọ̀rọ̀ eniyan lẹ́yìn, tí kò ṣe ibi sí ẹnìkejì rẹ̀, tí kò sì sọ ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn nípa aládùúgbò rẹ̀. 4 Ẹni tí kò ka ẹni ẹ̀kọ̀ sí, ṣugbọn a máa bu ọlá fún àwọn tí ó bẹ̀rù OLUWA; bí ó bá jẹ́ ẹ̀jẹ́, kì í yẹ̀ ẹ́; bí ẹ̀jẹ́ tí ó ti wù kí ó nira tó. 5 Kì í yáni lówó kí ó gba èlé, kìí sìí gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ́wọ́ aláìṣẹ̀. Ẹni tí ó bá ṣe nǹkan wọnyi, ẹsẹ̀ rẹ̀ kò ní yẹ̀ laelae. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria