O. Daf 149 - Yoruba BibleOrin Ìyìn sí OLUWA 1 Ẹ yin OLUWA! Ẹ kọ orin titun sí OLUWA, ẹ kọrin ìyìn sí i ninu àwùjọ àwọn olóòótọ́. 2 Kí Israẹli máa yọ̀ ninu Ẹlẹ́dàá rẹ̀, kí àwọn ọmọ Sioni máa fò fún ayọ̀ pé àwọn ní Ọba. 3 Kí wọn máa fi ijó yin orúkọ rẹ̀, kí wọn máa fi ìlù ati hapu kọ orin aládùn sí i. 4 Nítorí pé inú OLUWA dùn sí àwọn eniyan rẹ̀, a sì máa fi ìṣẹ́gun dé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ládé. 5 Kí àwọn olódodo máa ṣògo ninu ọlá; kí wọ́n máa kọrin ayọ̀ lórí ibùsùn wọn. 6 Kí wọn máa fi ohùn wọn yin Ọlọrun; kí idà olójú meji sì wà ní ọwọ́ wọn, 7 láti gbẹ̀san lára àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, ati láti jẹ àwọn eniyan wọn níyà; 8 láti fi ẹ̀wọ̀n de àwọn ọba orílẹ̀-èdè mìíràn, ati láti fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ de àwọn ọlọ́lá wọn; 9 láti ṣe ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀. Ògo gbogbo àwọn olódodo nìyí. Ẹ yin OLUWA! |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria