O. Daf 146 - Yoruba BibleGbẹ́kẹ̀lé OLUWA 1 Ẹ yin OLUWA! Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi. 2 N óo máa yin OLUWA níwọ̀n ìgbà tí mo wà láyé; n óo máa kọrin ìyìn sí Ọlọrun mi níwọ̀n ìgbà tí mo wà láàyè. 3 Má gbẹ́kẹ̀lé àwọn ìjòyè; eniyan ni wọ́n, kò sì sí ìgbàlà lọ́dọ̀ wọn. 4 Bí ẹ̀mí wọn bá ti bọ́, wọn á pada di erùpẹ̀, ní ọjọ́ náà sì ni èrò inú wọn óo di ègbé. 5 Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó fi Ọlọrun Jakọbu ṣe olùrànlọ́wọ́ rẹ̀, tí ó gbójú lé OLUWA, Ọlọrun rẹ̀. 6 Ọlọrun tí ó dá ọ̀run ati ayé, òkun ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀; Ọlọrun tíí máa ń pa àdéhùn rẹ̀ mọ́ títí lae, 7 ẹni tíí máa ń dá ẹjọ́ òdodo fún àwọn tí a ni lára; tí ń fún àwọn tí ebi ń pa ní oúnjẹ, OLUWA tíí tú àwọn tí ó wà ninu ìdè sílẹ̀. 8 A máa la ojú àwọn afọ́jú, a máa gbé àwọn tí a tẹrí wọn ba dúró; ó fẹ́ràn àwọn olódodo. 9 OLUWA ni olùṣọ́ àwọn àlejò, òun ni alátìlẹ́yìn àwọn opó ati aláìníbaba, ṣugbọn a máa da ète àwọn eniyan burúkú rú. 10 OLUWA yóo jọba títí lae, Sioni, Ọlọrun rẹ yóo jọba láti ìran dé ìran. Ẹ yin OLUWA. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria