Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

O. Daf 143 - Yoruba Bible


Adura Ìrànlọ́wọ́

1 OLUWA, gbọ́ adura mi; fetí sí ẹ̀bẹ̀ mi! Dá mi lóhùn ninu òtítọ́ ati òdodo rẹ.

2 Má dá èmi ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ lẹ́jọ́, nítorí pé kò sí ẹ̀dá alààyè tí ẹjọ́ rẹ̀ lè tọ́ níwájú rẹ.

3 Ọ̀tá ti lé mi bá, ó ti lù mí bolẹ̀; ó jù mí sinu òkùnkùn, bí ẹni tí ó ti kú tipẹ́tipẹ́.

4 Nítorí náà ọkàn mi rẹ̀wẹ̀sì; ọkàn mi sì pòrúúruù.

5 Mo ranti ìgbà àtijọ́, mo ṣe àṣàrò lórí gbogbo ohun tí o ti ṣe, mo sì ronú lórí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.

6 Mo na ọwọ́ sí ọ fún ìrànlọ́wọ́; bí òùngbẹ omi í tií gbẹ ilẹ̀ gbígbẹ, bẹ́ẹ̀ ni òùngbẹ rẹ ń gbẹ ọkàn mi.

7 OLUWA, yára dá mi lóhùn! Ẹ̀mí mi ti fẹ́rẹ̀ pin! Má fara pamọ́ fún mi, kí n má baà dàbí àwọn tí ó ti lọ sinu isà òkú.

8 Jẹ́ kí n máa ranti ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ láràárọ̀, nítorí ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé. Kọ́ mi ní ọ̀nà tí n óo máa rìn, nítorí pé ìwọ ni mo gbójú sókè sí.

9 OLUWA, gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi; ìwọ ni mo sá di.

10 Kọ́ mi láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ, nítorí pé ìwọ ni Ọlọrun mi. Jẹ́ kí ẹ̀mí rere rẹ máa tọ́ mi ní ọ̀nà tí ó tọ́.

11 Nítorí ti orúkọ rẹ, OLUWA, dá mi sí; ninu òtítọ́ rẹ, yọ mí ninu ìpọ́njú.

12 Ninu ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, pa àwọn ọ̀tá mi, kí o sì pa gbogbo àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi run, nítorí pé iranṣẹ rẹ ni mí.

Bible Society of Nigeria © 1900/2010

Bible Society of Nigeria
Lean sinn:



Sanasan