Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

O. Daf 142 - Yoruba Bible


Adura Ìrànlọ́wọ́

1 Mo ké pe OLUWA, mo gbé ohùn ẹ̀bẹ̀ sókè sí i.

2 Mo tú ẹ̀dùn ọkàn mi palẹ̀ níwájú rẹ̀, mo sọ ìṣòro mi fún un.

3 Nígbà tí ọkàn mi rẹ̀wẹ̀sì, ó mọ ọ̀nà tí mo lè gbà. Wọ́n ti dẹ tàkúté sílẹ̀ fún mi ní ọ̀nà tí mò ń rìn.

4 Mo wo ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún mi yíká, mo rí i pé kò sí ẹni tí ó náání mi; kò sí ààbò fún mi, ẹnikẹ́ni kò sì bìkítà fún mi.

5 Mo ké pè ọ́, OLUWA, mo ní, “Ìwọ ni ààbò mi, ìwọ ni ìpín mi lórí ilẹ̀ alààyè.”

6 Gbọ́ igbe mi; nítorí wọ́n ti rẹ̀ mí sílẹ̀ patapata. Gbà mí lọ́wọ́ àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi, nítorí pé wọ́n lágbára jù mí lọ.

7 Yọ mí kúrò ninu ìhámọ́, kí n lè yin orúkọ rẹ lógo. Àwọn olódodo yóo yí mi ká, nítorí ọpọlọpọ oore tí o óo ṣe fún mi.

Bible Society of Nigeria © 1900/2010

Bible Society of Nigeria
Lean sinn:



Sanasan