O. Daf 141 - Yoruba BibleAdura Ààbò 1 OLUWA, mo ké pè ọ́, tètè wá dá mi lóhùn, tẹ́tí sí ohùn mi nígbà tí mo bá ń ké pè ọ́. 2 Jẹ́ kí adura mi wá sí ọ̀dọ̀ rẹ bíi turari, sì jẹ́ kí ọwọ́ adura tí mo gbé sókè dàbí ẹbọ àṣáálẹ́. 3 OLUWA, fi ìjánu sí mi ní ẹnu, sì ṣe aṣọ́nà ètè mi. 4 Má jẹ́ kí ọkàn mi fà sí ibi, má sì jẹ́ kí n lọ́wọ́ sí iṣẹ́ ìkà. Má jẹ́ kí n bá àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ rìn pọ̀, má sì jẹ́ kí n jẹ ninu oúnjẹ àdídùn wọn. 5 N ò kọ̀ kí ẹni rere bá mi wí, n ò kọ̀ kí ó nà mí; kí ó ṣá ti fi ìfẹ́ bá mi wí. Ṣugbọn má jẹ́ kí eniyan burúkú tilẹ̀ ta òróró sí mi lórí, nítorí pé nígbàkúùgbà ni mò ń fi adura tako ìwà ibi wọn. 6 Nígbà tí ọwọ́ àwọn tí yóo dá wọn lẹ́bi bá tẹ̀ wọ́n, wọn óo gbà pé, òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ OLUWA. 7 Bí òkúta tí eniyan là, tí ó fọ́ yángá-yángá sílẹ̀, ni a óo fọ́n egungun wọn ká sí ẹnu ibojì. 8 Ṣugbọn ìwọ ni mo gbójúlé, OLUWA, Ọlọrun. Ìwọ ni asà mi, má fi mí sílẹ̀ láìní ààbò. 9 Pa mí mọ́ ninu ewu tàkúté, ati ti okùn tí àwọn aṣebi dẹ sílẹ̀ dè mí. 10 Jẹ́ kí àwọn eniyan burúkú ṣubú sinu àwọ̀n ara wọn, kí èmi sì lọ láìfarapa. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria