O. Daf 14 - Yoruba BibleÈrè Òmùgọ̀ 1 Òmùgọ̀ sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé, “Ọlọrun kò sí.” Wọ́n bàjẹ́, ohun ìríra ni iṣẹ́ ọwọ́ wọn, kò sì sí ẹnìkan ninu wọn tí ń ṣe rere. 2 OLUWA bojú wo ilẹ̀, láti ọ̀run wá, ó wo àwọn ọmọ eniyan, láti mọ̀ bí àwọn kan bá wà tí wọ́n gbọ́n, tí wọn ń wá Ọlọrun. 3 Gbogbo wọn ti ṣìnà, gbogbo wọn pátá ni wọ́n sì ti bàjẹ́; kò sí ẹnìkan tí ń ṣe rere, kò sí ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo. 4 Ṣé gbogbo àwọn aṣebi kò gbọ́n ni? Àwọn tí ń jẹ eniyan mi bí ẹni jẹun, àwọn tí kì í ké pe OLUWA. 5 Níbẹ̀ ni a óo ti dẹ́rù bà wọ́n gidigidi, nítorí Ọlọrun ń bẹ pẹlu àwọn olódodo. 6 Ẹ̀yin ń fẹ́ da ètò aláìní rú, ṣugbọn OLUWA ni ààbò rẹ̀. 7 Ìbá ti dára tó kí ìgbàlà Israẹli ti Sioni wá! Nígbà tí OLUWA bá dá ire àwọn eniyan rẹ̀ pada, Jakọbu yóo yọ̀, inú Israẹli yóo sì dùn. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria