Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

O. Daf 137 - Yoruba Bible


Àwọn Ọmọ Israẹli Kọrin Arò ní Ìgbèkùn

1 Lẹ́bàá odò Babiloni ni a jókòó, tí a sọkún, nígbà tí a ranti Sioni.

2 Lára igi wilo níbẹ̀ ni a fi hapu wa kọ́ sí,

3 nítorí pé níbẹ̀ ni àwọn tí ó kó wa ní ìgbèkùn ti ní kí á kọrin fún àwọn. Àwọn tí ó ń pọ́n wa lójú sọ pé kí á dá àwọn lárayá, wọ́n ní, “Ẹ kọ orin Sioni kan fún wa.”

4 Báwo ni a óo ṣe kọ orin OLUWA ní ilẹ̀ àjèjì?

5 Jerusalẹmu, bí mo bá gbàgbé rẹ, kí ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó rọ.

6 Kí ahọ́n mi lẹ̀ mọ́ èrìgì mi, bí n kò bá ranti rẹ, bí n kò bá sì fi Jerusalẹmu ṣe olórí ayọ̀ mi.

7 OLUWA, ranti ohun tí àwọn ará Edomu ṣe nígbà tí Jerusalẹmu bọ́ sọ́wọ́ ọ̀tá, tí wọn ń pariwo pé, “Ẹ wó o palẹ̀! Ẹ wó o palẹ̀! Ẹ wó o títí dé ìpìlẹ̀ rẹ̀.”

8 Babiloni! Ìwọ apanirun! Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá gbẹ̀san lára rẹ, fún gbogbo ohun tí o ti ṣe sí wa!

9 Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá kó àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ rẹ, tí ó ṣán wọn mọ́ àpáta.

Bible Society of Nigeria © 1900/2010

Bible Society of Nigeria
Lean sinn:



Sanasan