O. Daf 136 - Yoruba BibleOrin Ọpẹ́ 1 Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, nítorí pé ó ṣeun, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. 2 Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun tí ó ju gbogbo àwọn oriṣa lọ, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. 3 Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA tí ó ju gbogbo àwọn oluwa lọ, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. 4 Òun nìkan ṣoṣo ní ń ṣe iṣẹ́ ìyanu ńlá, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. 5 Ẹni tí ó fi ọgbọ́n dá ọ̀run, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; 6 ẹni tí ó tẹ́ ilẹ̀ lé orí omi, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; 7 ẹni tí ó dá àwọn ìmọ́lẹ̀ ńlá, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. 8 Ó dá oòrùn láti máa ṣe àkóso ọ̀sán, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. 9 Ó dá òṣùpá ati ìràwọ̀ láti máa ṣe àkóso òru, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. 10 Ẹni tí ó pa àwọn àkọ́bí ní ilẹ̀ Ijipti, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; 11 ó sì kó àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò láàrin wọn, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. 12 Pẹlu ipá ati ọwọ́ líle ni ó fi kó wọn jáde, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. 13 Ẹni tí ó pín Òkun Pupa sí meji, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; 14 ó sì mú àwọn ọmọ Israẹli kọjá láàrin rẹ̀, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; 15 ṣugbọn ó bi Farao ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ṣubú ninu Òkun Pupa, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. 16 Ẹni tí ó mú àwọn eniyan rẹ̀ la aṣálẹ̀ já, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; 17 ẹni tí ó pa àwọn ọba ńlá, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; 18 ó sì pa àwọn ọba olókìkí, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; 19 Sihoni ọba àwọn Amori, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; 20 ati Ogu ọba Baṣani, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. 21 Ó pín ilẹ̀ wọn fún àwọn eniyan rẹ̀, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; 22 ó fún àwọn ọmọ Israẹli, iranṣẹ rẹ̀, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. 23 Òun ni ó ranti wa ní ipò ìrẹ̀lẹ̀ wa, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; 24 ó sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. 25 Ẹni tí ó pèsè oúnjẹ fún gbogbo ẹ̀dá alààyè, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. 26 Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun ọ̀run, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria