1 Ẹ wá, ẹ yin OLUWA, gbogbo ẹ̀yin iranṣẹ rẹ̀, gbogbo ẹ̀yin tí ń sìn ín ninu ilé rẹ̀ lóru.
2 Ẹ gbé ọwọ́ yín sókè, kí ẹ gbadura ninu ilé mímọ́ rẹ̀, kí ẹ sì yin OLUWA.
3 Kí OLUWA tí ó dá ọ̀run ati ayé bukun yín láti Sioni wá.
Bible Society of Nigeria © 1900/2010