O. Daf 132 - Yoruba BibleMajẹmu Ọlọrun pẹlu Ìdílé Dafidi 1 OLUWA, ranti gbogbo ìyà tí Dafidi fara dà. 2 Ranti bí ó ṣe búra fún OLUWA, tí ó sì jẹ́jẹ̀ẹ́ fún ìwọ Alágbára, Ọlọrun Jakọbu, 3 tí ó ní, “N kò ní wọ inú ilé mi, bẹ́ẹ̀ ni n kò ní bọ́ sí orí ibùsùn mi; 4 n kò ní sùn, bẹ́ẹ̀ ni n kò ní tòògbé, 5 títí tí n óo fi wá ààyè fún OLUWA, àní, tí n óo fi pèsè ibùgbé fún ìwọ Alágbára, Ọlọrun Jakọbu.” 6 A gbúròó rẹ̀ ní Efurata, a rí i ní oko Jearimu. 7 “Ẹ jẹ́ kí á lọ sí ibùgbé rẹ̀; ẹ jẹ́ kí á lọ wólẹ̀ níbi àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀.” 8 Dìde, OLUWA, lọ sí ibi ìsinmi rẹ, tìwọ ti àpótí agbára rẹ. 9 Jẹ́ kí àwọn alufaa rẹ wọ ẹ̀wù òdodo, kí àwọn eniyan mímọ́ rẹ sì máa kọrin ayọ̀. 10 Nítorí ti Dafidi, iranṣẹ rẹ, má jẹ́ kí ẹni tí a fi òróró rẹ yàn yíjú kúrò lára rẹ. 11 OLUWA ti ṣe ìbúra tí ó dájú fún Dafidi, èyí tí kò ní yipada; ó ní, “Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹ ni n óo gbé ka orí ìtẹ́ rẹ. 12 Bí àwọn ọmọ rẹ bá pa majẹmu mi mọ́, tí wọ́n sì tẹ̀lé ìlànà tí n óo fi lélẹ̀ fún wọn, àwọn ọmọ tiwọn náà óo jókòó lórí ìtẹ́ rẹ títí lae.” 13 Nítorí OLUWA ti yan Sioni; ó fẹ́ ẹ fún ibùjókòó rẹ̀: 14 Ó ní, “Ìhín ni ibi ìsinmi mi títí lae, níhìn-ín ni n óo máa gbé, nítorí pé ó wù mí. 15 N óo bù sí oúnjẹ rẹ̀ lọpọlọpọ; n óo fi oúnjẹ tẹ́ àwọn aláìní ibẹ̀ lọ́rùn. 16 N óo gbé ẹ̀wù ìgbàlà wọ àwọn alufaa rẹ̀, àwọn eniyan mímọ́ rẹ̀ yóo sì kọrin ayọ̀. 17 Níbẹ̀ ni n óo ti fún Dafidi ní agbára; mo ti gbé àtùpà kalẹ̀ fún ẹni tí mo fi òróró yàn. 18 N óo da ìtìjú bo àwọn ọ̀tá rẹ̀ bí aṣọ, ṣugbọn adé orí rẹ̀ yóo máa tàn yinrinyinrin.” |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria