O. Daf 131 - Yoruba BibleÀṣírí ìfọ̀kànbalẹ̀ 1 OLUWA, n kò ṣe ìgbéraga, bẹ́ẹ̀ ni ojú mi kò gbé sókè. N ò dáwọ́ lé nǹkan ńláńlá, n ò sì dá àrà tí ó jù mí lọ. 2 Kàkà bẹ́ẹ̀, mo fi ara mi lọ́kàn balẹ̀, mo dákẹ́ jẹ́ẹ́, bí ọmọ ọwọ́ tíí dákẹ́ jẹ́ẹ́ láyà ìyá rẹ̀. Ọkàn mi balẹ̀ bíi ti ọmọ ọwọ́ tó dákẹ́ jẹ́ẹ́. 3 Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ ní ìrètí ninu OLUWA, láti ìsinsìnyìí lọ ati títí laelae. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria