O. Daf 130 - Yoruba BibleAdura Ẹlẹ́ṣẹ̀ 1 Ninu ìṣòro ńlá ni mò ń ké pè ọ́, OLUWA! 2 OLUWA, gbóhùn mi, dẹtí sí ohùn ẹ̀bẹ̀ mi. 3 Bí OLUWA bá ń sàmì ẹ̀ṣẹ̀, ta ló lè yege? 4 Ṣugbọn ní ìkáwọ́ rẹ ni ìdáríjì wà, kí á lè máa bẹ̀rù rẹ. 5 Mo gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, àní, mo gbé ọkàn mi lé e, mo sì ní ìrètí ninu ọ̀rọ̀ rẹ̀. 6 Mò ń retí rẹ, OLUWA, ju bí àwọn aṣọ́de ti máa ń retí kí ilẹ̀ mọ́ lọ, àní, ju bí àwọn aṣọ́de, ti máa ń retí pé kí ilẹ̀ mọ́. 7 Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ ní ìrètí ninu OLUWA! Nítorí pé ní ìkáwọ́ rẹ̀ ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ wà, ní ìkáwọ́ rẹ̀ sì ni ìràpadà kíkún wà. 8 Òun óo sì ra Israẹli pada kúrò ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria