O. Daf 127 - Yoruba BibleAbániṣé ni OLUWA 1 Bí OLUWA kò bá kọ́ ilé, asán ni wahala àwọn tí ń kọ́ ọ. Bí OLUWA kò bá ṣọ́ ìlú, asán ni àìsùn àwọn aṣọ́de. 2 Asán ni kí á jí ní òwúrọ̀ kutukutu, kí á tún pẹ́ títí kí á tó sùn. Asán ni kí á máa fi làálàá wá oúnjẹ; nítorí pé OLUWA a máa fún àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ ní oorun sùn. 3 Wò ó! Ẹ̀bùn OLUWA ni ọmọ; òun ní fi oyún inú ṣìkẹ́ eniyan. 4 Bí ọfà ti rí lọ́wọ́ jagunjagun, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ ìgbà òwúrọ̀ ẹni. 5 Ayọ̀ ń bẹ fun ẹni tí apó rẹ̀ kún fún wọn. Ojú kò ní tì í nígbà tí ó bá ń bá àwọn ọ̀tá rẹ̀ rojọ́ lẹ́nu bodè. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria