O. Daf 126 - Yoruba BibleẸkún Di Ayọ̀ 1 Nígbà tí OLUWA kó àwọn ìgbèkùn Sioni pada, ó dàbí àlá lójú wa. 2 Ẹ̀rẹ̀kẹ́ wa kún fún ẹ̀rín, a sì kọrin ayọ̀, nígbà náà ni àwọn orílẹ̀-èdè yòókù ń wí pé, “OLUWA mà ṣe nǹkan ńlá fún àwọn eniyan yìí!” 3 Lóòótọ́, OLUWA ṣe nǹkan ńlá fún wa, nítorí náà à ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀. 4 Dá ire wa pada, OLUWA, bí ìṣàn omi ní ipadò aṣálẹ̀ Nẹgẹbu. 5 Àwọn tí ń fọ́n irúgbìn pẹlu omi lójú, jẹ́ kí wọn kórè rẹ̀ tayọ̀tayọ̀. 6 Ẹni tí ń gbé irúgbìn lọ sí oko tẹkúntẹkún, yóo ru ìtí ọkà pada sílé tayọ̀tayọ̀. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria