O. Daf 124 - Yoruba BibleỌlọrun Aláàbò Àwọn Eniyan Rẹ̀ 1 Tí kì í bá ṣe pé OLUWA tí ó wà lẹ́yìn wa, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ wí pé, 2 “Tí kì í bá ṣe pé OLUWA tí ó wà lẹ́yìn wa nígbà tí ọmọ aráyé gbógun tì wá, 3 wọn ìbá gbé wa mì láàyè, nígbà tí inú bí wọn sí wa; 4 àgbàrá ìbá ti gbá wa lọ, ìṣàn omi ìbá ti bò wá mọ́lẹ̀; 5 ìgbì omi ìbá ti gbé wa mì.” 6 Ọpẹ́ ni fún OLUWA, tí kò fi wá ṣe ẹran ìjẹ fún wọn. 7 A ti yọ, bí ẹyẹ tí ó yọ ninu okùn apẹyẹ: okùn ti já; àwa sì ti yọ. 8 Ọ̀dọ̀ OLUWA ni ìrànlọ́wọ́ wa ti wá, ẹni tí ó dá ọ̀run ati ayé. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria