O. Daf 122 - Yoruba BibleÌyìn Jerusalẹmu 1 Inú mi dùn nígbà tí wọ́n wí fún mi pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ sí ilé OLUWA.” 2 A ti tẹsẹ̀ bọ inú ìgboro rẹ, Jerusalẹmu. 3 Jerusalẹmu, ìlú ńlá tí a kọ́, tí gbogbo rẹ̀ já pọ̀ di ọ̀kan. 4 Níbi tí àwọn ẹ̀yà, àní, àwọn ẹ̀yà eniyan OLUWA máa ń gòkè lọ, láti dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí a pa fún Israẹli. 5 Níbẹ̀ ni a tẹ́ ìtẹ́ ìdájọ́ sí, àní, ìtẹ́ ìdájọ́ àwọn ọba ìdílé Dafidi. 6 Gbadura fún alaafia Jerusalẹmu! “Yóo dára fún àwọn tí ó fẹ́ràn rẹ! 7 Kí alaafia ó wà ninu rẹ, kí ìbàlẹ̀ àyà wà ninu ilé ìṣọ́ rẹ.” 8 Nítorí ti àwọn ará ati àwọn ẹlẹgbẹ́ mi, n óo wí pé, “Kí alaafia ó wà ninu rẹ.” 9 Nítorí ti ilé OLUWA, Ọlọrun wa, èmi óo máa wá ire rẹ. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria