O. Daf 121 - Yoruba BibleOLUWA Aláàbò Wa 1 Mo gbójú sókè wo àwọn òkè, níbo ni ìrànlọ́wọ́ mi ti ń wá? 2 Ìrànlọ́wọ́ mi ń ti ọ̀dọ̀ OLUWA wá, ẹni tí ó dá ọ̀run ati ayé. 3 Kò ní jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ ó yẹ̀, ẹni tí ń pa ọ́ mọ́ kò ní tòògbé. 4 Wò ó, ẹni tí ń pa Israẹli mọ́ kò ní tòògbé, bẹ́ẹ̀ ni kò ní sùn. 5 OLUWA ni olùpamọ́ rẹ. OLUWA yóo ṣíji bò ọ́ ní apá ọ̀tún rẹ. 6 Oòrùn kò ní ṣe ọ́ léṣe lọ́sàn-án, bẹ́ẹ̀ ni òṣùpá kò ní pa ọ́ lára lóru. 7 OLUWA óo dáàbò bò ọ́ lọ́wọ́ gbogbo ibi, yóo pa ọ́ mọ́. 8 OLUWA yóo pa àlọ ati ààbọ̀ rẹ mọ́, láti ìsinsìnyìí lọ ati títí lae. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria