O. Daf 12 - Yoruba BibleAdura Ìrànlọ́wọ́ 1 Gbani, OLUWA; nítorí àwọn olódodo kò sí mọ́; àwọn olóòótọ́ ti pòórá láàrin àwọn ọmọ eniyan. 2 Olukuluku ń purọ́ fún ẹnìkejì rẹ̀; ọ̀rọ̀ ìpọ́nni èké ati ẹ̀tàn ni wọ́n ń bá ara wọn sọ. 3 Kí OLUWA pa gbogbo àwọn tí ń fi èké pọ́nni run, ati àwọn tí ń fọ́nnu, 4 àwọn tí ń wí pé, “Ẹnu wa yìí ni a óo fi ṣẹgun, àwa la ni ẹnu wa; ta ni ó lè mú wa?” 5 OLUWA wí pé, “Nítorí ìnira àwọn aláìṣẹ̀, ati nítorí ìkérora àwọn tí à ń pọ́n lójú, n óo dìde nisinsinyii, n óo sì dáàbò bò wọ́n bí ọkàn wọn ti ń fẹ́.” 6 Ìlérí tó dájú ni ìlérí OLUWA, ó dàbí fadaka tí a yọ́ ninu iná ìléru amọ̀, tí a dà ninu iná nígbà meje. 7 Dáàbò bò wá, OLUWA, pa wá mọ́ laelae kúrò lọ́wọ́ irú àwọn eniyan báwọ̀nyí. 8 Àwọn eniyan burúkú ń yan kiri, níwọ̀n ìgbà tí àwọn eniyan ń ṣe àpọ́nlé iṣẹ́ ibi. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria